Jeremiah 25:15-16

Ago ìbínú Ọlọ́run

15 aÈyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí fún mi: “Gba ago yìí ní ọwọ́ mí tí ó kún fún ọtí wáìnì ìbínú mi, kí o sì mú gbogbo orílẹ̀-èdè ti mo rán ọ sí mu ún. 16Nígbà tí wọ́n bá mu ún, wọn yóò ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n: bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n di aṣiwèrè nítorí idà tí yóò ránṣẹ́ sí àárín wọn.”
Copyright information for YorBMYO